O. Daf 80:1-19

O. Daf 80:1-19 Bibeli Mimọ (YBCV)

FI eti si ni, Oluṣọ-agutan Israeli, iwọ ti o ndà Josefu bi ọwọ́-agutan; iwọ ti o joko lãrin awọn kerubu tàn imọlẹ jade. Niwaju Efraimu ati Benjamini ati Manasse rú ipa rẹ soke ki o si wá fun igbala wa. Tún wa yipada, Ọlọrun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là. Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, iwọ o ti binu pẹ to si adura awọn enia rẹ? Iwọ fi onjẹ omije bọ́ wọn; iwọ si fun wọn li omije mu li ọ̀pọlọpọ. Iwọ sọ wa di ijà fun awọn aladugbo wa: awọn ọta wa si nrẹrin ninu ara wọn. Tún wa yipada, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o si mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là. Iwọ ti mu ajara kan jade ti Egipti wá: iwọ ti tì awọn keferi jade, iwọ si gbin i. Iwọ ṣe àye silẹ fun u, iwọ si mu u ta gbòngbo jinlẹ̀, o si kún ilẹ na. A fi ojiji rẹ̀ bò awọn òke mọlẹ, ati ẹka rẹ̀ dabi igi kedari Ọlọrun. O yọ ẹka rẹ̀ sinu okun, ati ọwọ rẹ̀ si odò nla nì. Ẽṣe ti iwọ ha fi ya ọgbà rẹ̀ bẹ̃, ti gbogbo awọn ẹniti nkọja lọ li ọ̀na nká a? Imado lati inu igbo wá mba a jẹ, ati ẹranko igbẹ njẹ ẹ run. Yipada, awa mbẹ ọ, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: wolẹ lati ọrun wá, ki o si wò o, ki o si bẹ àjara yi wò: Ati agbala-àjara ti ọwọ ọtún rẹ ti gbin, ati ọmọ ti iwọ ti mule fun ara rẹ. O jona, a ke e lulẹ: nwọn ṣegbe nipa ibawi oju rẹ. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o wà lara ọkunrin ọwọ ọtún rẹ nì, lara ọmọ-enia ti iwọ ti mule fun ara rẹ. Bẹ̃li awa kì yio pada sẹhin kuro lọdọ rẹ: mu wa yè, awa o si ma pè orukọ rẹ. Tún wa yipada, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, mu oju rẹ tàn imọlẹ; a o si gbà wa là.

O. Daf 80:1-19 Yoruba Bible (YCE)

Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli, Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran. Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́ níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase. Sọ agbára rẹ jí, kí o sì wá gbà wá là. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun; fi ojurere wò wá, kí á le gbà wá là. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí adura àwọn eniyan rẹ? O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ, o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó. O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa; àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn. Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun; fi ojurere wò wá, kí á lè là. O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti; o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín. O ro ilẹ̀ fún un; ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀. Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀, ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun, àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá. Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀, tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ sì fi ń ká èso rẹ̀? Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun, gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́. Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun! Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó; kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí, ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn, àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú. Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀; fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé! Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú, àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára. Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ; dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́! Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun! Fi ojurere wò wá, kí á lè là!

O. Daf 80:1-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli; ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran; ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase. Ru agbára rẹ̀ sókè; wá fún ìgbàlà wa. Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run; jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí a bá à lè gbà wá là. OLúWA Ọlọ́run alágbára, ìbínú rẹ̀ yóò ti pẹ́ tó sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ? Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ìwọ sọ wá di ẹlẹ́yà fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn ọ̀tá wa sì ń yọ̀ wá. Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára; jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa, kí a ba à lè gbà wá là. Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti; ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín. Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un, ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀ ó sì kún ilẹ̀ náà. A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run. O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun, ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì. Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀ tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀? Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́ àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run. Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára! Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó! Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò, Gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn, àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ. A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún; ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ. Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ; mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ. Tún wa yípadà, OLúWA Ọlọ́run alágbára; kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa, kí á ba à lè gbà wá là.