O. Daf 77:11-15
O. Daf 77:11-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o ranti iṣẹ Oluwa: nitõtọ emi o ranti iṣẹ iyanu rẹ atijọ. Ṣugbọn emi o ma ṣe àṣaro gbogbo iṣẹ rẹ pẹlu, emi o si ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ. Ọlọrun, ọ̀na rẹ mbẹ ninu ìwa-mimọ́: tali alagbara ti o tobi bi Ọlọrun? Iwọ li Alagbara ti nṣe iṣẹ iyanu: iwọ li o ti fi ipá rẹ hàn ninu awọn enia. Iwọ li o ti fi apá rẹ rà awọn enia rẹ pada, awọn ọmọ Jakobu ati Josefu.
O. Daf 77:11-15 Yoruba Bible (YCE)
N óo ranti àwọn iṣẹ́ OLUWA, àní, n óo ranti àwọn iṣẹ́ ìyanu ìgbàanì. N óo máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ; n óo sì máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ ribiribi tí o ṣe. Ọlọrun, mímọ́ ni ọ̀nà rẹ; oriṣa wo ni ó tó Ọlọrun wa? Ìwọ ni Ọlọrun tí ń ṣe ohun ìyanu; o ti fi agbára rẹ hàn láàrin àwọn eniyan. O ti fi agbára rẹ gba àwọn eniyan rẹ là; àní, àwọn ọmọ Jakọbu ati Josẹfu.
O. Daf 77:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ó rántí iṣẹ́ OLúWA: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́. Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ. Ọlọ́run, Ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa? Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela.