O. Daf 73:21-28
O. Daf 73:21-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi ni inu mi bajẹ, ẹgún si gun mi li ọkàn mi. Bẹ̃ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ̀ nkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ. Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigbagbogbo: iwọ li o ti di ọwọ ọtún mi mu. Iwọ o fi ìmọ rẹ tọ́ mi li ọ̀na, ati nigbẹhin iwọ o gbà mi sinu ogo. Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ. Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai. Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ. Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo.
O. Daf 73:21-28 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́, tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi, mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye, mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ; o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà; lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo. Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ? Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi, ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi, ati ìpín mi títí lae. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé, o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun; mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi, kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.
O. Daf 73:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi ṣì korò, Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ. Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ. Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé. Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run; tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run Èmi ti fi OLúWA Olódùmarè ṣe ààbò mi; Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.