O. Daf 73:16-28
O. Daf 73:16-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati mo rò lati mọ̀ eyi, o ṣoro li oju mi. Titi mo fi lọ sinu ibi-mimọ́ Ọlọrun; nigbana ni mo mọ̀ igbẹhin wọn. Nitõtọ iwọ gbé wọn ka ibi yiyọ́: iwọ tì wọn ṣubu sinu iparun. Bawo li a ti mu wọn lọ sinu idahoro yi, bi ẹnipe ni iṣẹju kan! ibẹru li a fi nrun wọn patapata. Bi igbati ẹnikan ba ji li oju alá; bẹ̃ni Oluwa, nigbati iwọ ba ji, iwọ o ṣe àbuku àworan wọn. Bayi ni inu mi bajẹ, ẹgún si gun mi li ọkàn mi. Bẹ̃ni mo ṣiwere, ti emi kò si mọ̀ nkan; mo dabi ẹranko niwaju rẹ. Ṣugbọn emi wà pẹlu rẹ nigbagbogbo: iwọ li o ti di ọwọ ọtún mi mu. Iwọ o fi ìmọ rẹ tọ́ mi li ọ̀na, ati nigbẹhin iwọ o gbà mi sinu ogo. Tani mo ni li ọrun bikoṣe iwọ? kò si si ohun ti mo fẹ li aiye pẹlu rẹ. Ẹran-ara mi ati aiya mi di ãrẹ̀ tan: ṣugbọn Ọlọrun ni apata aiya mi, ati ipin mi lailai. Sa wò o, awọn ti o jina si ọ yio ṣegbe: iwọ ti pa gbogbo wọn run ti nṣe àgbere kiri kuro lọdọ rẹ. Ṣugbọn o dara fun mi lati sunmọ Ọlọrun: emi ti gbẹkẹ mi le Oluwa Ọlọrun, ki emi ki o le ma sọ̀rọ iṣẹ rẹ gbogbo.
O. Daf 73:16-28 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn nígbà tí mo rò bí nǹkan wọnyi ṣe lè yé mi, mo rí i pé iṣẹ́ tíí dáni lágara ni. Àfi ìgbà tí mo wọ ibi mímọ́ Ọlọrun lọ, ni mo tó wá rí òye ìgbẹ̀yìn wọn. Nítòótọ́ ibi tí ń yọ̀ ni ó gbé wọn lé, ó sì mú kí wọn ṣubú sinu ìparun. Wò ó bí wọn ṣe parun lọ́gán, tí ìpayà sì gbá wọn lọ patapata. Wọ́n dàbí àlá tíí pòórá nígbà tí eniyan bá ta jí. OLUWA, nígbà tí o bá jí gìrì, wọn óo pòórá. Nígbà tí ọkàn mí bàjẹ́, tí ọ̀rọ̀ náà gbóná lára mi, mo hùwà òmùgọ̀, n kò sì lóye, mo sì dàbí ẹranko lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. Sibẹsibẹ nígbà gbogbo ni mo wà lọ́dọ̀ rẹ; o sì di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ò ń fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi sọ́nà; lẹ́yìn náà, o óo sì gbà mí sinu ògo. Ta ni mo ní lọ́run lẹ́yìn rẹ? Kò sì sí ohun kan tí ó wù mí láyé yìí bíkòṣe ìwọ. Àárẹ̀ lè mú ara ati ẹ̀mí mi, ṣugbọn Ọlọrun ni agbára ẹ̀mí mi, ati ìpín mi títí lae. Ó dájú pé àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóo ṣègbé, o óo sì pa àwọn tí ó bá ṣe alaiṣootọ sí ọ run. Ní tèmi o, ó dára láti súnmọ́ Ọlọrun; mo ti fi ìwọ OLUWA Ọlọrun ṣe ààbò mi, kí n lè máa ròyìn gbogbo iṣẹ́ rẹ.
O. Daf 73:16-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi. Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi. Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun. Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá! Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, OLúWA, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn. Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi ṣì korò, Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ. Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ? Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ. Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé. Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé ìwọ ti pa gbogbo wọn run; tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run Èmi ti fi OLúWA Olódùmarè ṣe ààbò mi; Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.