O. Daf 73:1-8
O. Daf 73:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITÕTỌ Ọlọrun ṣeun fun Israeli, fun iru awọn ti iṣe alaiya mimọ́. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, ẹsẹ mi fẹrẹ yẹ̀ tan; ìrin mi fẹrẹ yọ́ tan. Nitori ti emi ṣe ilara si awọn aṣe-fefe, nigbati mo ri alafia awọn enia buburu. Nitoriti kò si irora ninu ikú wọn: agbara wọn si pọ̀. Nwọn kò ni ipin ninu iyọnu enia; bẹ̃ni a kò si wahala wọn pẹlu ẹlomiran. Nitorina ni igberaga ṣe ká wọn lọrun bi ẹ̀wọn ọṣọ́; ìwa-ipa bò wọn mọlẹ bi aṣọ. Oju wọn yọ jade fun isanra: nwọn ní jù bi ọkàn wọn ti nfẹ lọ. Nwọn nṣẹsin, nwọn si nsọ̀rọ buburu niti inilara: nwọn nsọ̀rọ lati ibi giga.
O. Daf 73:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli, ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́. Ṣugbọn, ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ yọ̀ ṣubú, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tàsé. Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Wọn kì í jẹ ìrora kankan, ara wọn dá pé, ó sì jọ̀lọ̀. Wọn kì í ní wahala bí àwọn ẹlòmíràn; ìyọnu tíí dé bá àwọn ẹlòmíràn kì í dé ọ̀dọ̀ wọn. Nítorí náà, wọn á kó ìgbéraga bọ ọrùn bí ẹ̀gbà, wọn á fi ìwà ipá bora bí aṣọ. Wọ́n sanra tóbẹ́ẹ̀ tí ojú wọn yíbò; èrò òmùgọ̀ sì kún ọkàn wọn ní àkúnwọ́sílẹ̀. Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara; wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.
O. Daf 73:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli, fún àwọn ọlọ́kàn funfun. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán; ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán. Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú. Wọn kò ṣe wàhálà; ara wọn mókun wọn sì lágbára. Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn; a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn. Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn; ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ. Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá; ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.