O. Daf 72:1-20

O. Daf 72:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌLỌRUN, fi idajọ rẹ fun ọba, ati ododo rẹ fun ọmọ ọba. On o ma fi ododo ṣe idajọ awọn enia rẹ, yio si ma fi ẹtọ́ ṣe idajọ awọn talaka rẹ. Awọn òke nla yio ma mu alafia fun awọn enia wá, ati awọn òke kekeke nipa ododo. On o ma ṣe idajọ awọn talaka enia, yio ma gbà awọn ọmọ awọn alaini, yio si fà aninilara ya pẹrẹ-pẹrẹ. Nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ, niwọ̀n bi õrùn ati oṣupa yio ti pẹ to, lati irandiran. On o rọ̀ si ilẹ bi ojò si ori koriko itẹ̀mọlẹ: bi ọwọ òjo ti o rin ilẹ. Li ọjọ rẹ̀ li awọn olododo yio gbilẹ: ati ọ̀pọlopọ alafia niwọn bi òṣupa yio ti pẹ to. On o si jọba lati okun de okun, ati lati odò nì de opin aiye. Awọn ti o joko li aginju yio tẹriba fun u; awọn ọta rẹ̀ yio si lá erupẹ ilẹ. Awọn ọba Tarṣiṣi, ati ti awọn erekuṣu yio mu ọrẹ wá: awọn ọba Ṣeba ati ti Seba yio mu ẹ̀bun wá. Nitõtọ, gbogbo awọn ọba ni yio wolẹ niwaju rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma sìn i. Nitori yio gbà alaini nigbati o ba nke: talaka pẹlu, ati ẹniti kò li oluranlọwọ. On o da talaka ati alaini si, yio si gbà ọkàn awọn alaini là. On o rà ọkàn wọn pada lọwọ ẹ̀tan ati ìwa-agbara: iyebiye si li ẹ̀jẹ wọn li oju rẹ̀. On o si yè, on li a o si fi wura Ṣeba fun: a o si ma gbadura fun u nigbagbogbo: lojojumọ li a o si ma yìn i. Ikúnwọ ọkà ni yio ma wà lori ilẹ, lori awọn òke nla li eso rẹ̀ yio ma mì bi Lebanoni: ati awọn ti inu ilu yio si ma gbà bi koriko ilẹ. Orukọ rẹ̀ yio wà titi lai: orukọ rẹ̀ yio ma gbilẹ niwọn bi õrun yio ti pẹ to: nwọn o si ma bukún fun ara wọn nipaṣẹ rẹ̀: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio ma pè e li alabukúnfun. Olubukún li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun Israeli, ẹnikanṣoṣo ti nṣe ohun iyanu. Olubukún li orukọ rẹ̀ ti o li ogo titi lai: ki gbogbo aiye ki o si kún fun ogo rẹ̀. Amin, Amin. Adura Dafidi ọmọ Jesse pari.

O. Daf 72:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́; kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ. Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ, kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́; kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia, kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké. Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ; kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀; kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú. Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ. Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti gé àní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀. Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀; kí alaafia ó gbilẹ̀ títí tí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́. Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun, ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé. Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un; àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀. Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogbo yóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un; àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀; a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀, ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka, a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá, ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn, a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ, a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo; a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru. Ọkà yóo pọ̀ lóko, yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè; èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni, eniyan yóo pọ̀ ní ìlú, bíi koríko ninu pápá. Orúkọ ọba óo wà títí lae, òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn; àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn, gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire. Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe. Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí, kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan! Amin! Amin. Níbi tí adura Dafidi ọmọ Jese parí sí nìyí.

O. Daf 72:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Fi ìdájọ́ fún àwọn ọba, Ọlọ́run, ọmọ-aládé ni ìwọ fi òdodo rẹ fún Yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú òdodo, yóò sì máa fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn tálákà rẹ̀. Àwọn òkè ńlá yóò máa mú àlàáfíà fún àwọn ènìyàn àti òkè kéékèèkéé nípa òdodo Yóò dáàbò bo àwọn tí a pọ́n lójú láàrín àwọn ènìyàn yóò gba àwọn ọmọ aláìní; yóò sì fa àwọn aninilára ya. Àwọn òtòṣì àti aláìní yóò máa fi ọ̀wọ̀ ńlá fún ọ nígbà gbogbo, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn àti òṣùpá bá ń ràn, yóò ti pẹ́ tó, láti ìrandíran. Yóò dàbí òjò tí ó ń rọ̀ sórí pápá ìrẹ́mọ́lẹ̀ Bí ọwọ́ òjò tó ń rin ilẹ̀ Àwọn olódodo yóò gbilẹ̀ ni ọjọ́ rẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yóò sì wà; títí tí òṣùpá kò fi ní sí mọ́. Yóò máa jẹ ọba láti Òkun dé Òkun àti láti odò Eufurate títí dé òpin ayé. Àwọn tí ó wà ní aginjù yóò tẹríba fún un àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò máa lá erùpẹ̀ ilẹ̀. Àwọn ọba Tarṣiṣi àti ti erékùṣù wọn yóò mú ọrẹ wá fún un; àwọn ọba Ṣeba àti Seba wọn ó mú ẹ̀bùn wá fún un. Gbogbo ọba yóò tẹríba fún un àti gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sìn ín. Nítorí yóò gba àwọn aláìní nígbà tí ó bá ń ké, tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò káàánú àwọn aláìlera àti aláìní yóò pa aláìní mọ́ kúrò nínú ikú. Yóò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ipá nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn ṣọ̀wọ́n níwájú rẹ̀. Yóò sì pẹ́ ní ayé! A ó sì fún un ní wúrà Ṣeba. Àwọn ènìyàn yóò sì máa gbàdúrà fún un nígbà gbogbo kí a sì bùkún fún un lójoojúmọ́. Kí ìkúnwọ́ ọkà wà lórí ilẹ̀; ní orí òkè ni kí ó máa dàgbà kí èso rẹ̀ kí o gbilẹ̀ bí ti Lebanoni yóò máa gbá yìn bí i koríko ilẹ̀. Kí orúkọ rẹ̀ kí ó wà títí láé; orúkọ rẹ̀ yóò máa gbilẹ̀ níwọ̀n bí oòrùn yóò ti pẹ́ tó. Wọn ó sì máa bùkún fún ara wọn nípasẹ̀ rẹ. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní yóò máa pè mí ní alábùkún fún. Olùbùkún ni OLúWA Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli, ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń ṣe ohun ìyanu. Olùbùkún ni orúkọ rẹ̀ tí ó lógo títí láé; kí gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀. Àmín àti Àmín. Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.