ORIN DAFIDI 72:1-20

ORIN DAFIDI 72:1-20 YCE

Ọlọrun, gbé ìlànà òtítọ́ rẹ lé ọba lọ́wọ́; kọ́ ọmọ ọba ní ọ̀nà òdodo rẹ. Kí ó lè máa fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ, kí ó sì máa dá ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ ní ọ̀nà ẹ̀tọ́; kí àwọn eniyan tí ó gbé orí òkè ńlá lè rí alaafia, kí nǹkan sì dára fún àwọn tí ń gbé orí òkè kéékèèké. Jẹ́ kí ó máa gbèjà àwọn eniyan tí ìyà ń jẹ; kí ó máa gba àwọn ọmọ talaka sílẹ̀; kí ó sì rún àwọn aninilára wómúwómú. Ọlọrun, jẹ́ kí àwọn eniyan rẹ máa bẹ̀rù rẹ láti ìran dé ìran, níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn, tí òṣùpá sì ń yọ. Jẹ́ kí ọba ó dàbí òjò tí ó rọ̀ sórí koríko tí a ti gé àní, bí ọ̀wààrà òjò tí ń rin ilẹ̀. Kí ìwà rere ó gbèrú ní ìgbà tirẹ̀; kí alaafia ó gbilẹ̀ títí tí òṣùpá kò fi ní yọ mọ́. Kí ìjọba rẹ̀ ó lọ láti òkun dé òkun, ati láti odò ńlá títí dé òpin ayé. Àwọn tí ń gbé aṣálẹ̀ yóo máa foríbalẹ̀ fún un; àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo sì máa fi ẹnu gbo ilẹ̀ níwájú rẹ̀. Àwọn ọba Taṣiṣi ati àwọn ọba erékùṣù gbogbo yóo máa san ìṣákọ́lẹ̀ fún un; àwọn ọba Ṣeba ati ti Seba yóo máa mú ẹ̀bùn wá. Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín. Nítorí pé a máa gba talaka tí ó bá ké pè é sílẹ̀; a sì máa gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀, ati àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. A máa ṣíjú àánú wo àwọn aláìní ati talaka, a sì máa gba àwọn talaka sílẹ̀. A máa gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn aninilára ati oníwà ipá, ẹ̀mí wọn sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ yóo gùn, a óo máa fi wúrà Ṣeba ta á lọ́rẹ, a óo máa gbadura fún un nígbà gbogbo; a óo sì máa súre fún un tọ̀sán-tòru. Ọkà yóo pọ̀ lóko, yóo máa mì lẹ̀gbẹ̀ lórí òkè; èso rẹ̀ yóo dàbí ti Lẹbanoni, eniyan yóo pọ̀ ní ìlú, bíi koríko ninu pápá. Orúkọ ọba óo wà títí lae, òkìkí rẹ̀ óo sì máa kàn níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń ràn; àwọn eniyan óo máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún ara wọn, gbogbo orílẹ̀-èdè óo sì máa pè é ní olóríire. Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe. Ẹni ìyìn títí lae ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ lókìkí, kí òkìkí rẹ̀ gba ayé kan! Amin! Amin. Níbi tí adura Dafidi ọmọ Jese parí sí nìyí.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ORIN DAFIDI 72:1-20