O. Daf 71:3-6
O. Daf 71:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ ni ki o ṣe ibujoko apata mi, nibiti emi o gbe ma rè nigbagbogbo: iwọ ti paṣẹ lati gbà mi; nitori iwọ li apata ati odi agbara mi. Gbà mi, Ọlọrun mi, li ọwọ awọn enia buburu, li ọwọ alaiṣododo ati ìka ọkunrin. Nitori iwọ ni ireti mi, Oluwa Ọlọrun; iwọ ni igbẹkẹle mi lati igba ewe mi. Ọwọ rẹ li a ti fi gbé mi duro lati inu wá: iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu iya mi wá: nipasẹ rẹ ni iyìn mi wà nigbagbogbo.
O. Daf 71:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Máa ṣe àpáta ààbò fún mi, jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí, nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi. Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, àwọn alaiṣootọ ati ìkà. Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi. Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún; ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi. Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.
O. Daf 71:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jẹ́ àpáta ààbò mi, níbi tí èmi lè máa lọ, pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi. Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú, ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin. Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, OLúWA Olódùmarè, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe. Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.