ORIN DAFIDI 71

71
Adura Àgbàlagbà kan
1OLUWA, ìwọ ni mo sá di;
má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae!
2Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;
tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!
3Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,
jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,
nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.
4Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,
àwọn alaiṣootọ ati ìkà.
5Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi,
OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi.
6Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún;
ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi.
Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo.
7Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan,
ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
8Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,
ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru.
9Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi;
má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́.
10Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi,
àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀,
11wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
ẹ lé e, ẹ mú un;
nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.”
12Ọlọrun, má jìnnà sí mi;
yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́!
13Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun;
kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
14Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo,
n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́.
15N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ,
n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru,
nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn.
16N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun,
n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan.
17Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi,
títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ,
18Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi,
Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀,
títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ,
àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀.
19Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run,
ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá,
Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ?
20O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá,
ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò;
óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú.
21O óo fi kún ọlá mi,
o óo sì tún tù mí ninu.
22Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́,
nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi;
n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́,
ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23N óo máa kígbe fún ayọ̀,
nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ;
ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀.
24Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru,
nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
a sì ti dójú tì wọ́n.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 71: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa