O. Daf 71:21-23
O. Daf 71:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Iwọ o sọ ọlá mi di pupọ̀, iwọ o si tù mi ninu niha gbogbo. Emi o si fi ohun-elo orin yìn ọ pẹlu, ani otitọ rẹ, Ọlọrun mi: iwọ li emi o ma fi duru kọrin si, iwọ Ẹni-Mimọ́ Israeli. Ete mi yio yọ̀ gidigidi, nigbati mo ba nkọrin si ọ: ati ọkàn mi, ti iwọ ti rapada.
O. Daf 71:21-23 Yoruba Bible (YCE)
O óo fi kún ọlá mi, o óo sì tún tù mí ninu. Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́, nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi; n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́, ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. N óo máa kígbe fún ayọ̀, nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ; ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀.
O. Daf 71:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo. Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ: èmi, ẹni tí o rà padà.