O. Daf 71:1-24

O. Daf 71:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: lai máṣe jẹ ki a dãmu mi. Gbà mi nipa ododo rẹ, ki o si mu mi yọ̀: dẹ eti rẹ si mi, ki o si gbà mi. Iwọ ni ki o ṣe ibujoko apata mi, nibiti emi o gbe ma rè nigbagbogbo: iwọ ti paṣẹ lati gbà mi; nitori iwọ li apata ati odi agbara mi. Gbà mi, Ọlọrun mi, li ọwọ awọn enia buburu, li ọwọ alaiṣododo ati ìka ọkunrin. Nitori iwọ ni ireti mi, Oluwa Ọlọrun; iwọ ni igbẹkẹle mi lati igba ewe mi. Ọwọ rẹ li a ti fi gbé mi duro lati inu wá: iwọ li ẹniti o mu mi jade lati inu iya mi wá: nipasẹ rẹ ni iyìn mi wà nigbagbogbo. Emi dabi ẹni-iyanu fun ọ̀pọlọpọ enia, ṣugbọn iwọ li àbo mi ti o lagbara. Jẹ ki ẹnu mi ki o kún fun iyìn rẹ ati fun ọlá rẹ li ọjọ gbogbo. Máṣe ṣa mi ti ni ìgba ogbó; máṣe kọ̀ mi silẹ nigbati agbara mi ba yẹ̀. Nitori awọn ọta mi nsọ̀rọ si mi; awọn ti nṣọ ọkàn mi si gbimọ̀ pọ̀. Nwọn wipe, Ọlọrun ti kọ̀ ọ silẹ: ẹ lepa ki ẹ si mu u; nitori ti kò si ẹniti yio gbà a. Ọlọrun, máṣe jina si mi: Ọlọrun mi, yara si iranlọwọ mi. Jẹ ki nwọn ki o dãmu, ki a si run awọn ti nṣe ọta ọkàn mi, ki a si fi ẹ̀gan ati àbuku bo awọn ti nwá ifarapa mi. Ṣugbọn emi o ma reti nigbagbogbo, emi o si ma fi iyìn kún iyìn rẹ. Ẹnu mi yio ma fi ododo rẹ ati igbala rẹ hàn li ọjọ gbogbo; emi kò sa mọ̀ iye rẹ̀. Emi o wá li agbara Oluwa Ọlọrun; emi o ma da ọ̀rọ ododo rẹ sọ, ani tirẹ nikan. Ọlọrun, iwọ ti kọ́ mi lati igba ewe mi wá: ati di isisiyi li emi ti nsọ̀rọ iṣẹ iyanu rẹ. Pẹlupẹlu, nigbati emi di arugbo tan ti mo hewu, Ọlọrun máṣe kọ̀ mi; titi emi o fi fi ipá rẹ hàn fun iran yi, ati agbara rẹ fun gbogbo awọn ara ẹ̀hin. Ọlọrun ododo rẹ ga jọjọ pẹlu, ẹniti o ti nṣe nkan nla: Ọlọrun, tali o dabi iwọ! Iwọ ti o fi iṣẹ nla ati kikan hàn mi, ni yio si tun mi ji, yio si tun mu mi sọ si òke lati ọgbun ilẹ wá. Iwọ o sọ ọlá mi di pupọ̀, iwọ o si tù mi ninu niha gbogbo. Emi o si fi ohun-elo orin yìn ọ pẹlu, ani otitọ rẹ, Ọlọrun mi: iwọ li emi o ma fi duru kọrin si, iwọ Ẹni-Mimọ́ Israeli. Ete mi yio yọ̀ gidigidi, nigbati mo ba nkọrin si ọ: ati ọkàn mi, ti iwọ ti rapada. Ahọn mi pẹlu yio si ma sọ̀rọ ododo rẹ titi li ọjọ gbogbo: nitoriti nwọn dãmu, a si doju ti awọn tí nwá ifarapa mi.

O. Daf 71:1-24 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA, ìwọ ni mo sá di; má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae! Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ; tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là! Máa ṣe àpáta ààbò fún mi, jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí, nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi. Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, àwọn alaiṣootọ ati ìkà. Nítorí ìwọ OLUWA, ni ìrètí mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé láti ìgbà èwe mi. Ìwọ ni mo gbára lé láti inú oyún; ìwọ ni o mú mi jáde láti inú ìyá mi. Ìwọ ni n óo máa yìn nígbà gbogbo. Mo di ẹni àmúpòwe fún ọpọlọpọ eniyan, ṣugbọn ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára. Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ, ó kún fún ògo rẹ tọ̀sán-tòru. Má ta mí nù ní ìgbà ogbó mi; má sì gbàgbé mi nígbà tí n kò bá lágbára mọ́. Nítorí pé àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi, àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi ti pàmọ̀ pọ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; ẹ lé e, ẹ mú un; nítorí kò sí ẹni tí yóo gbà á sílẹ̀ mọ́.” Ọlọrun, má jìnnà sí mi; yára, Ọlọrun mi, ràn mí lọ́wọ́! Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn alátakò mi, kí wọn parun; kí ẹ̀gàn ati ìtìjú bo àwọn tí ń wá ìpalára mi. Ní tèmi, èmi ó máa ní ìrètí nígbà gbogbo, n óo sì túbọ̀ máa yìn ọ́. N óo máa ṣírò iṣẹ́ rere rẹ, n óo máa ròyìn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ tọ̀sán-tòru, nítorí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè mọ iye wọn. N óo wá ninu agbára OLUWA Ọlọrun, n óo máa kéde iṣẹ́ òdodo rẹ, àní, iṣẹ́ òdodo tìrẹ nìkan. Ọlọrun, láti ìgbà èwe mi ni o ti kọ́ mi, títí di òní ni mo sì ń polongo iṣẹ́ ìyanu rẹ, Nisinsinyii tí mo ti dàgbà, tí ewú sì ti gba orí mi, Ọlọrun, má kọ̀ mí sílẹ̀, títí tí n óo fi ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ, àní, iṣẹ́ agbára rẹ, fún gbogbo àwọn ìran tí ń bọ̀. Ọlọrun, iṣẹ́ òdodo rẹ kan ojú ọ̀run, ìwọ tí o ṣe nǹkan ńlá, Ọlọrun, ta ni ó dàbí rẹ? O ti jẹ́ kí n rí ọpọlọpọ ìpọ́njú ńlá, ṣugbọn óo tún mú ìgbé ayé mi pada bọ̀ sípò; óo tún ti gbé mi dìde láti inú isà òkú. O óo fi kún ọlá mi, o óo sì tún tù mí ninu. Èmi náà óo máa fi hapu yìn ọ́, nítorí òtítọ́ rẹ, Ọlọrun mi; n óo máa fi ohun èlò orin yìn ọ́, ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. N óo máa kígbe fún ayọ̀, nígbà tí mo bá ń kọ orin ìyìn sí ọ; ẹ̀mí mi tí o ti kó yọ, yóo ké igbe ayọ̀. Ẹnu mi yóo ròyìn iṣẹ́ rẹ tọ̀sán-tòru, nítorí a ti ṣẹgun àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì ti dójú tì wọ́n.

O. Daf 71:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nínú rẹ, OLúWA, ni mo ní ààbò; Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí. Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ; dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí. Jẹ́ àpáta ààbò mi, níbi tí èmi lè máa lọ, pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi. Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú, ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin. Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, OLúWA Olódùmarè, ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe. Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi; Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá èmi ó máa yìn ọ́ títí láé. Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára. Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo. Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́ Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi, àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀. Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu, nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.” Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run; wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́. Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú, kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù bo àwọn tí ń wá ìpalára mi. Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi; èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i. Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀. Èmi ó wá láti wá kéde agbára, OLúWA Olódùmarè; èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan. Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ. Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú, Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi, títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀, àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn. Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run, ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run? Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀ Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo. Èmi yóò fi dùùrù mi yìn fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi; èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli. Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ: èmi, ẹni tí o rà padà. Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́, fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára, a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.