O. Daf 64:1-10
O. Daf 64:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, gbohùn mi ninu aroye mi: pa ẹmi mi mọ́ lọwọ ẹ̀ru ọta nì. Pa mi mọ́ lọwọ ìmọ ìkọkọ awọn enia buburu: lọwọ irukerudo awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ. Ẹniti npọ̀n ahọn wọn bi ẹnipe idà, ti nwọn si fa ọrun wọn le lati tafa wọn, ani ọ̀rọ kikoro: Ki nwọn ki o le ma tafà ni ìkọkọ si awọn ti o pé: lojiji ni nwọn tafa si i, nwọn kò si bẹ̀ru. Nwọn gba ara wọn niyanju li ọ̀ran buburu: nwọn gbìmọ ati dẹkun silẹ nikọ̀kọ; nwọn wipe, Tani yio ri wọn? Nwọn gbero ẹ̀ṣẹ; nwọn wipe, awa ti pari ero ti a gbà tan: ati ìro inu olukuluku wọn, ati aiya wọn, o jinlẹ. Ṣugbọn Ọlọrun yio tafà si wọn lojiji; nwọn o si gbọgbẹ. Bẹ̃ni ahọn wọn yio mu wọn ṣubu lu ara wọn: gbogbo ẹniti o ri wọn yio mì ori wọn. Ati gbogbo enia ni yio ma bẹ̀ru, nwọn o si ma sọ̀rọ iṣẹ Ọlọrun; nitoriti nwọn o fi ọgbọ́n rò iṣẹ rẹ̀. Olododo yio ma yọ̀ nipa ti Oluwa, yio si ma gbẹkẹle e; ati gbogbo ẹni-iduro-ṣinṣin li aiya ni yio ma ṣogo.
O. Daf 64:1-10 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun, gbọ́ ìráhùn mi; pa mí mọ́ lọ́wọ́ ìdẹ́rùbà ọ̀tá; dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan burúkú; kó mi yọ lọ́wọ́ ète àwọn aṣebi. Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà, wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ burúkú bí ẹni ta ọfà; wọ́n ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí aláìṣẹ̀ láti ibùba wọn, láìbẹ̀rù, wọ́n ń ta ọfà ọ̀rọ̀ sí i lójijì. Wọ́n wonkoko mọ́ ète burúkú wọn; wọ́n ń gbìmọ̀ àtidẹ okùn sílẹ̀ níkọ̀kọ̀, wọ́n ń rò lọ́kàn wọn pé, “Ta ni yóo rí wa? Ta ni yóo wá ẹ̀ṣẹ̀ wa rí? Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni a ti fi pète.” Áà, inú ọmọ eniyan jìn! Ṣugbọn Ọlọrun yóo ta wọ́n lọ́fà; wọn óo fara gbọgbẹ́ lójijì. Yóo pa wọ́n run nítorí ohun tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ; gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn ni yóo máa mirí nítorí wọn. Ẹ̀rù yóo sì ba gbogbo eniyan; wọn yóo máa sọ ohun tí Ọlọrun ti gbé ṣe, wọn yóo sì máa ronú nípa iṣẹ́ rẹ̀. Kí àwọn olódodo máa yọ̀ ninu OLUWA, kí wọ́n sì máa wá ààbò lọ́dọ̀ rẹ̀! Kí gbogbo ẹni pípé máa ṣògo.
O. Daf 64:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá. Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà, wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò. Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀: wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù. Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú, wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀ wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?” Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé, “A wa ti parí èrò tí a gbà tán” lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà; wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì. Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n, Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn. Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe. Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú OLúWA yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀. Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.