O. Daf 63:3-6
O. Daf 63:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ. Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ. Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ: Nigbati mo ba ranti rẹ lori ẹní mi, ti emi si nṣe aṣaro rẹ ni iṣọ oru.
O. Daf 63:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ, n óo máa yìn ọ́. N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi; n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ. Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù; n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ. Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi, tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru
O. Daf 63:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ. Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ. A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́. Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.