O. Daf 63:2-5
O. Daf 63:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ. Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ. Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ. Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ
O. Daf 63:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ, mo ti rí agbára ati ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ, n óo máa yìn ọ́. N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi; n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ. Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù; n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ.
O. Daf 63:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ. Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ. A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.