O. Daf 63:1-11
O. Daf 63:1-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, iwọ li Ọlọrun mi; ni kutukutu li emi o ma ṣafẹri rẹ; ongbẹ rẹ ngbẹ ọkàn mi, ẹran-ara mi fà si ọ ni ilẹ gbigbẹ, ati ilẹ ti npongbẹ, nibiti omi kò gbe si. Bayi li emi ti wò ọ ninu ibi-mimọ́, lati ri agbara rẹ ati ogo rẹ. Nitori ti iṣeun-ifẹ rẹ san jù ìye lọ, ète mi yio ma yìn ọ. Bayi li emi o ma fi ibukún fun ọ niwọnbi mo ti wà lãye: emi o ma gbé ọwọ mi soke li orukọ rẹ. Bi ẹnipe ijà ati ọ̀ra bẹ̃ni yio tẹ ọkàn mi lọrun; ẹnu mi yio si ma fi ète ayọ̀ yìn ọ: Nigbati mo ba ranti rẹ lori ẹní mi, ti emi si nṣe aṣaro rẹ ni iṣọ oru. Nitoripe iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi, nitorina li ojiji iyẹ́-apa rẹ li emi o ma yọ̀. Ọkàn mi ntọ̀ ọ lẹhin girigiri: ọwọ ọtún rẹ li o gbé mi ró. Ṣugbọn awọn ti nwá ọkàn mi lati pa a run, nwọn o lọ si iha isalẹ-ilẹ. Nwọn o ti ọwọ idà ṣubu: nwọn o si ṣe ijẹ fun kọ̀lọkọlọ. Ṣugbọn ọba yio ma yọ̀ ninu Ọlọrun; olukuluku ẹniti o nfi i bura ni yio ṣogo: ṣugbọn awọn ti nṣeke li a o pa li ẹnu mọ́.
O. Daf 63:1-11 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ, ọkàn rẹ ń fà mí; bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹ ṣe máa ń kóǹgbẹ omi. Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ, mo ti rí agbára ati ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ, n óo máa yìn ọ́. N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi; n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ. Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù; n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ. Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi, tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru; nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi, lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin. Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ; ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró. Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi yóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú. A ó fi idà pa wọ́n lójú ogun, ẹranko ni yóo sì jẹ òkú wọn. Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun; gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búra yóo máa fògo fún un; ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́.
O. Daf 63:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ, òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi, ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi. Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́, mo rí agbára àti ògo rẹ. Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ, ètè mi yóò fògo fún ọ. Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ. A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ; pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́. Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru. Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi, mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Ọkàn mí fà sí ọ: ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró. Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun; wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé. Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀. Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.