O. Daf 62:5-8
O. Daf 62:5-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọkàn mi, iwọ sa duro jẹ de Ọlọrun; nitori lati ọdọ rẹ̀ wá ni ireti mi. On nikan li apata mi ati igbala mi: on li àbo mi; a kì yio ṣi mi ni ipò. Nipa Ọlọrun ni igbala mi, ati ogo mi: apata agbara mi, àbo mi si mbẹ ninu Ọlọrun. Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa.
O. Daf 62:5-8 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà; òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan; ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀; OLUWA ni ààbò wa.
O. Daf 62:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò. Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi. Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa.