O. Daf 62:1-12
O. Daf 62:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN nikan li ọkàn mi duro jẹ dè; lati ọdọ rẹ̀ wá ni igbala mi. On nikan li apata mi ati igbala mi; on li àbo mi, emi kì yio ṣipò pada jọjọ. Ẹnyin o ti ma rọlu enia kan pẹ to? gbogbo nyin li o fẹ pa a: bi ogiri ti o bìwó ati bi ọgbà ti nwó lọ. Kiki ìro wọn ni lati já a tilẹ kuro ninu ọlá rẹ̀: nwọn nṣe inu didùn ninu eke: nwọn nfi ẹnu wọn sure, ṣugbọn nwọn ngegun ni inu wọn. Ọkàn mi, iwọ sa duro jẹ de Ọlọrun; nitori lati ọdọ rẹ̀ wá ni ireti mi. On nikan li apata mi ati igbala mi: on li àbo mi; a kì yio ṣi mi ni ipò. Nipa Ọlọrun ni igbala mi, ati ogo mi: apata agbara mi, àbo mi si mbẹ ninu Ọlọrun. Gbẹkẹle e nigbagbogbo; ẹnyin enia, tú ọkàn nyin jade niwaju rẹ̀; Ọlọrun àbo fun wa. Nitõtọ asan li awọn ọmọ enia, eke si li awọn oloyè. Nwọn gòke ninu ìwọn, bakanna ni nwọn fẹrẹ jù asan lọ. Máṣe gbẹkẹle inilara, ki o má si ṣe gberaga li olè jija: bi ọrọ̀ ba npọ̀ si i, máṣe gbe ọkàn nyin le e. Ọlọrun ti sọ̀rọ lẹ̃kan; lẹ̃rinkeji ni mo gbọ́ eyi pe: ti Ọlọrun li agbara. Pẹlupẹlu, Oluwa, tirẹ li ãnu: nitoriti iwọ san a fun olukulùku enia gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀.
O. Daf 62:1-12 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé; ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìgbàlà mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Yóo ti pẹ́ tó, tí gbogbo yín yóo dojú kọ ẹnìkan ṣoṣo, láti pa, ẹni tí kò lágbára ju ògiri tí ó ti fẹ́ wó lọ, tabi ọgbà tí ó fẹ́ ya? Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀. Inú wọn a máa dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́. Ọlọrun nìkan ni mo fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá. Òun nìkan ni àpáta ati olùgbàlà mi, òun ni odi mi, a kì yóo tì mí kúrò. Ọwọ́ Ọlọrun ni ìgbàlà ati ògo mi wà; òun ni àpáta agbára mi ati ààbò mi. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé e nígbà gbogbo, ẹ̀yin eniyan; ẹ tú ẹ̀dùn ọkàn yín palẹ̀ níwájú rẹ̀; OLUWA ni ààbò wa. Afẹ́fẹ́ lásán ni àwọn mẹ̀kúnnù; ìtànjẹ patapata sì ni àwọn ọlọ́lá; bí a bá gbé wọn lé ìwọ̀n, wọn kò lè tẹ̀wọ̀n; àpapọ̀ wọn fúyẹ́ ju afẹ́fẹ́ lọ. Má gbẹ́kẹ̀lé ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà, má sì fi olè jíjà yangàn; bí ọrọ̀ bá ń pọ̀ sí i, má gbé ọkàn rẹ lé e. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ níbìkan, mo sì ti gbọ́ ọ bí ìgbà mélòó kan pé, Ọlọrun ló ni agbára; ati pé, tìrẹ, OLUWA ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Ò máa san ẹ̀san fún eniyan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.
O. Daf 62:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú Ọlọ́run nìkan ni ọkàn mi ti rí ìsinmi; ìgbàlà mi ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Òun nìkan ní àpáta mi àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò sí mi ní ipò padà. Ẹ̀yin ó ti máa kọ́lú ènìyàn kan pẹ́ tó? Gbogbo yín ni ó fẹ́ pa á, bí ògiri tí ó fẹ́ yẹ̀, àti bí ọgbà tí ń wó lọ? Kìkì èrò wọn ni láti bì ṣubú kúrò nínú ọlá rẹ̀; inú wọn dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣùgbọ́n wọ́n ń gégùn ún nínú ọkàn wọn. Sela. Nínú Ọlọ́run nìkan ni ìsinmi wà, ìwọ Ọlọ́run mi. Ìrètí mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ. Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò. Ìgbàlà mi àti ògo mi dúró nínú Ọlọ́run; Òun ní àpáta ńlá mi, àti ààbò mi. Gbẹ́kẹ̀lé ní gbogbo ìgbà, ẹ̀yin ènìyàn; tú ọkàn rẹ jáde sí i, nítorí Ọlọ́run ni ààbò wa. Nítòótọ́, asán ni àwọn ọmọ ènìyàn, èké sì ni àwọn olóyè, wọ́n gòkè nínú ìwọ̀n, lápapọ̀ wọ́n jẹ́ èémí. Má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ìnilára, tàbí gbéraga nínú olè jíjà, nítòótọ́ bí ọrọ̀ rẹ̀ ń pọ̀ sí i, má ṣe gbẹ́kẹ̀ rẹ lé wọn. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì, ni mo gbọ́ èyí pé, ti Ọlọ́run ni agbára Pẹ̀lúpẹ̀lú, OLúWA, tìrẹ ni àánú nítorí tí ìwọ san án fún olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.