O. Daf 61:1-8
O. Daf 61:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi. Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ. Nitori iwọ li o ti nṣe àbo fun mi, ati ile-iṣọ agbara lọwọ ọta nì. Emi o joko ninu agọ rẹ lailai: jẹ ki emi ri àbo ni iyẹ-apa rẹ. Nitoripe iwọ, Ọlọrun, li o ti gbọ́ ẹjẹ́ mi: iwọ ti fi ogún awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ fun mi. Iwọ o fa ẹmi ọba gùn: ati ọjọ ọdun rẹ̀ bi atiran-diran. On o ma gbe iwaju Ọlọrun lailai; pèse ãnu ati otitọ, ti yio ma ṣe itọju rẹ̀. Bẹ̃li emi o ma kọrin iyìn si orukọ rẹ lailai, ki emi ki o le ma san ẹjẹ́ mi li ojojumọ.
O. Daf 61:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun, fetí sí adura mi. Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́, nígbà tí àárẹ̀ mú mi. Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ, nítorí ìwọ ni ààbò mi, ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbára láti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá. Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae, kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ. Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́; o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn; kí ó pẹ́ láyé kánrinkése. Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae; máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ. Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae, nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ.
O. Daf 61:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; Tẹ́tí sí àdúrà mi. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ. Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá. Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ. Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run; Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn, ọdún rẹ̀ fún ìrandíran. Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé; pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ. Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.