O. Daf 61:1-4
O. Daf 61:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBỌ́ ẹkún mi, Ọlọrun; fiye si adura mi. Lati opin aiye wá li emi o kigbe pè ọ, nigbati o rẹ̀ aiya mi, fà mi lọ si apata ti o ga jù mi lọ. Nitori iwọ li o ti nṣe àbo fun mi, ati ile-iṣọ agbara lọwọ ọta nì. Emi o joko ninu agọ rẹ lailai: jẹ ki emi ri àbo ni iyẹ-apa rẹ.
O. Daf 61:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun, fetí sí adura mi. Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́, nígbà tí àárẹ̀ mú mi. Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ, nítorí ìwọ ni ààbò mi, ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbára láti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá. Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae, kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ.
O. Daf 61:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run; Tẹ́tí sí àdúrà mi. Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́, mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀; mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ. Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi, ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá. Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.