O. Daf 59:1-17

O. Daf 59:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌLỌRUN mi, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: dãbobo mi lọwọ awọn ti o dide si mi. Gbà mi lọwọ awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ki o si gbà mi silẹ lọwọ awọn enia-ẹ̀jẹ. Sa kiyesi i, nwọn ba ni buba fun ọkàn mi, awọn alagbara pejọ si mi; kì iṣe nitori irekọja mi, tabi nitori ẹ̀ṣẹ mi, Oluwa. Nwọn sure, nwọn mura li aiṣẹ mi: dide lati pade mi, ki o si kiyesi i. Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni. Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka. Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́? Ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio rẹrin wọn: iwọ ni yio yọṣuti si gbogbo awọn keferi. Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi. Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi. Máṣe pa wọn, ki awọn enia mi ki o má ba gbagbe: tú wọn ká nipa agbara rẹ; ki o si sọ̀ wọn kalẹ, Oluwa asà wa. Nitori ẹ̀ṣẹ ẹnu wọn ni ọ̀rọ ète wọn, ki a mu wọn ninu igberaga wọn: ati nitori ẽbu ati èke ti nwọn nṣe. Run wọn ni ibinu, run wọn, ki nwọn ki o má ṣe si mọ́: ki o si jẹ ki nwọn ki o mọ̀ pe, Ọlọrun li olori ni Jakobu titi o fi de opin aiye. Ati li aṣalẹ jẹ ki nwọn ki o pada; ki nwọn ki o pariwo bi ajá, ki nwọn ki o si ma yi ilu na ka kiri. Jẹ ki nwọn ki o ma rìn soke rìn sodò fun ohun jijẹ, bi nwọn kò ba yó, nwọn o duro ni gbogbo oru na. Ṣugbọn emi o kọrin agbara rẹ; nitõtọ, emi o kọrin ãnu rẹ kikan li owurọ: nitori pe iwọ li o ti nṣe àbo ati ibi-asala mi li ọjọ ipọnju mi. Iwọ, agbara mi, li emi o kọrin si: nitori Ọlọrun li àbo mi, Ọlọrun ánu mi!

O. Daf 59:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi, Ọlọrun mi; dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì mí. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn apànìyàn. Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí! OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọ láti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò. Láìjẹ́ pé mo ṣẹ̀, wọ́n ń sáré kiri, wọ́n múra dè mí. Paradà, wá ràn mí lọ́wọ́, kí o sì rí i fúnra rẹ. Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà; má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi. Ní alaalẹ́, wọn á pada wá, wọn á máa hu bí ajá, wọn a sì máa kiri ìlú. Ẹ gbọ́ ohun tí wọn ń sọ jáde lẹ́nu, ẹ wo ahọ́n wọn bí idà; wọ́n sì ń wí ninu ara wọn pé, “Ta ni yóo gbọ́ ohun tí à ń sọ?” Ṣugbọn ìwọ OLUWA ń fi wọ́n rẹ́rìn-ín, o sì ń fi gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe yẹ̀yẹ́. Ọlọrun, agbára mi, ojú rẹ ni mò ń wò, nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi. Ọlọrun mi óo wá sọ́dọ̀ mi ninu ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀; Ọlọrun óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi. Má pa wọ́n, kí àwọn eniyan mi má baà gbàgbé; fi ọwọ́ agbára rẹ mì wọ́n, ré wọn lulẹ̀, OLUWA, ààbò wa! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn dá, àní, nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ẹnu wọn sọ, jẹ́ kí ìgbéraga wọn kó bá wọn. Nítorí èpè tí wọ́n ṣẹ́ ati irọ́ tí wọ́n pa, fi ibinu pa wọ́n run. Pa wọ́n run kí wọn má sí mọ́, kí àwọn eniyan lè mọ̀ pé Ọlọrun jọba lórí Jakọbu, ati títí dé òpin ayé. Ní alaalẹ́ wọn á pada wá wọn á máa hu bí ajá, wọn á sì máa kiri ìlú. Wọn á máa fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀, wọn á máa wá oúnjẹ kiri, bí wọn ò bá sì yó wọn á máa kùn. Ṣugbọn èmi ó kọrin ìyìn agbára rẹ; n óo kọrin sókè lówùúrọ̀, nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Nítorí ìwọ ni o ti jẹ́ odi mi ìwọ sì ni ààbò mi nígbà ìpọ́njú. Ọlọrun, agbára mi, n óo kọ orin ìyìn fún ọ, nítorí ìwọ, Ọlọrun, ni odi mi, Ọlọrun tí ó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn mí.

O. Daf 59:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi, Ọlọ́run; dáàbò bò mí kúrò lọ́dọ̀ àwọn tí ó dìde sí mi. Gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ búburú kí o sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí ń pòǹgbẹ ẹ̀jẹ̀. Wò ó, bí wọ́n ṣe ba ní bùba dè mí! Àwọn alágbára ń gbìmọ̀ lòdì sí mi Kì í ṣe nítorí ìrékọjá mi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ mí, OLúWA. Èmi kò ṣe àìṣedéédéé kan, síbẹ̀ wọ́n sáré wọ́n ṣetán láti kọlù mí. Dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi, kí o sì wo àìlera mi. OLúWA Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli, dìde fún ara rẹ kí o sì bá àwọn orílẹ̀-èdè wí; má ṣe ṣàánú fún àwọn olùrékọjá búburú nì. Sela. Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọ́n ń gbó bí àwọn ajá, wọ́n ń rìn yí ìlú náà káàkiri. Kíyèsi ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu: wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn, wọ́n sì wí pé, “Ta ni ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?” Ṣùgbọ́n ìwọ, OLúWA, yóò fi wọ́n rẹ́rìn-ín Ìwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ; nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi, Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi. Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi. Yóò sì jẹ́ kí n yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi. Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa, kí àwọn ènìyàn mi má ba à gbàgbé. Nínú agbára rẹ, jẹ́ kí wọn máa rìn kiri, kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn, ní ọ̀rọ̀ ètè wọn, kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn. Nítorí èébú àti èké tí wọn ń sọ, Pa wọ́n run nínú ìbínú, run wọ́n di ìgbà tí wọn kò ní sí mọ́. Nígbà náà ni yóò di mí mọ̀ dé òpin ayé pé Ọlọ́run jẹ ọba lórí Jakọbu. Sela. Wọ́n padà ní àṣálẹ́, wọn ń gbó bí àwọn ajá wọ́n ń rin ìlú náà káàkiri. Wọ́n ń rin kiri fún oúnjẹ wọ́n sì ń yán nígbà tí wọn kò yó. Ṣùgbọ́n èmi ó kọrin agbára rẹ, n ó kọrin ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀; nítorí ìwọ ni ààbò mi, ibi ìsádi mi ní ìgbà ìpọ́njú. Ìwọ agbára mi, èmi ó kọrin ìyìn sí ọ; ìwọ, Ọlọ́run, ààbò mi, Ọlọ́run ìfẹ́ mi.