ỌLỌRUN mi, gbà mi lọwọ awọn ọta mi: dãbobo mi lọwọ awọn ti o dide si mi.
Gbà mi lọwọ awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ, ki o si gbà mi silẹ lọwọ awọn enia-ẹ̀jẹ.
Sa kiyesi i, nwọn ba ni buba fun ọkàn mi, awọn alagbara pejọ si mi; kì iṣe nitori irekọja mi, tabi nitori ẹ̀ṣẹ mi, Oluwa.
Nwọn sure, nwọn mura li aiṣẹ mi: dide lati pade mi, ki o si kiyesi i.
Nitorina iwọ, Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, jí lati bẹ̀ gbogbo awọn keferi wò; máṣe ṣãnu fun olurekọja buburu wọnni.
Nwọn pada li aṣalẹ: nwọn npariwo bi ajá, nwọn nrìn yi ilu na ka.
Kiyesi i, nwọn nfi ẹnu wọn gùfẹ jade: idà wà li ète wọn: nitoriti nwọn nwipe, tali o gbọ́?
Ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio rẹrin wọn: iwọ ni yio yọṣuti si gbogbo awọn keferi.
Agbara rẹ̀ li emi o duro tì: nitori Ọlọrun li àbo mi.
Ọlọrun ãnu mi ni yio ṣaju mi: Ọlọrun yio jẹ ki emi ri ifẹ mi lara awọn ọta mi.
Máṣe pa wọn, ki awọn enia mi ki o má ba gbagbe: tú wọn ká nipa agbara rẹ; ki o si sọ̀ wọn kalẹ, Oluwa asà wa.
Nitori ẹ̀ṣẹ ẹnu wọn ni ọ̀rọ ète wọn, ki a mu wọn ninu igberaga wọn: ati nitori ẽbu ati èke ti nwọn nṣe.
Run wọn ni ibinu, run wọn, ki nwọn ki o má ṣe si mọ́: ki o si jẹ ki nwọn ki o mọ̀ pe, Ọlọrun li olori ni Jakobu titi o fi de opin aiye.
Ati li aṣalẹ jẹ ki nwọn ki o pada; ki nwọn ki o pariwo bi ajá, ki nwọn ki o si ma yi ilu na ka kiri.
Jẹ ki nwọn ki o ma rìn soke rìn sodò fun ohun jijẹ, bi nwọn kò ba yó, nwọn o duro ni gbogbo oru na.
Ṣugbọn emi o kọrin agbara rẹ; nitõtọ, emi o kọrin ãnu rẹ kikan li owurọ: nitori pe iwọ li o ti nṣe àbo ati ibi-asala mi li ọjọ ipọnju mi.
Iwọ, agbara mi, li emi o kọrin si: nitori Ọlọrun li àbo mi, Ọlọrun ánu mi!