O. Daf 38:11-22
O. Daf 38:11-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn olufẹ ati awọn ọrẹ mi duro li òkere kuro ni ìna mi, ati awọn ibatan mi duro li òkere rére. Awọn pẹlu ti nwá ọkàn mi dẹkùn silẹ fun mi; ati awọn ti nwá ifarapa mi nsọ̀rọ ohun buburu, nwọn si ngbiro ẹ̀tan li gbogbo ọjọ. Ṣugbọn emi, bi aditi, emi kò gbọ́; ati bi odi ti kò ya ẹnu rẹ̀. Bẹ̃ni mo dabi ọkunrin ti kò gbọ́ran, ati li ẹnu ẹniti iyàn kò si. Nitori, Oluwa, iwọ li emi duro dè, iwọ o gbọ́, Oluwa Ọlọrun mi. Nitori ti mo wipe, Gbohùn mi, ki nwọn ki o má ba yọ̀ mi; nigbati ẹsẹ mi ba yọ́, nwọn o ma gbé ara wọn ga si mi. Emi ti mura ati ṣubu, ikãnu mi si mbẹ nigbagbogbo niwaju mi. Nitori ti emi o jẹwọ ẹ̀ṣẹ mi; emi o kãnu nitori ẹ̀ṣẹ mi. Ṣugbọn ara yá awọn ọta mi, ara wọn le; awọn ti o korira mi lodi npọ̀ si i. Awọn ti o si nfi buburu san rere li ọta mi; nitori emi ntọpa ohun ti iṣe rere. Oluwa, máṣe kọ̀ mi silẹ; Ọlọrun mi, máṣe jina si mi. Yara lati ran mi lọwọ, Oluwa igbala mi.
O. Daf 38:11-22 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọ̀rẹ́ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi takété sí mi nítorí àrùn mi, àwọn ẹbí mi sì dúró lókèèrè réré. Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí, àwọn tí ń wá ìpalára mi ń sọ̀rọ̀ ìparun mi, wọ́n sì ń pète àrékérekè tọ̀sán-tòru. Ṣugbọn mo ṣe bí adití, n kò gbọ́, mo dàbí odi tí kò le sọ̀rọ̀. Àní, mo dàbí ẹni tí kò gbọ́rọ̀, tí kò sì ní àwíjàre kan lẹ́nu. Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè; OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn. Nítorí tí mò ń gbadura pé, kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mí nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀. Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú, mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo. Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi, mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi. Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí lágbára, àwọn tí ó kórìíra mi láìtọ́ sì pọ̀. Àwọn tí ń fi ibi san oore fún mi ní ń gbógun tì mí, nítorí pé rere ni mò ń ṣe. OLUWA, má kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọrun mi, má jìnnà sí mi. Yára wá ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, ìgbàlà mi.
O. Daf 38:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi, àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè. Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi; àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun, wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́. Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀; àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀. Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀, àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn. Ṣùgbọ́n sí ọ OLúWA, ìwọ ni mo dúró dè; ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn. Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí; nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.” Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú, ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo. Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi; àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi. Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì. Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi àwọn ni ọ̀tá mi nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn. Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ OLúWA! Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi. Yára láti ràn mí lọ́wọ́, OLúWA, Olùgbàlà mi.