O. Daf 38:1-10
O. Daf 38:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, máṣe ba mi wi ninu ibinu rẹ: bẹ̃ni ki o máṣe nà mi ni gbigbona ibinujẹ rẹ. Nitori ti ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ rẹ si kì mi wọ̀ mọlẹ. Kò si ibi yíyè li ara mi nitori ibinu rẹ; bẹ̃ni kò si alafia li egungun mi nitori ẹ̀ṣẹ mi. Nitori ti ẹbi ẹ̀ṣẹ mi bori mi mọlẹ, bi ẹrù wuwo, o wuwo jù fun mi. Ọgbẹ mi nrùn, o si dibajẹ nitori were mi. Emi njowere; ori mi tẹ̀ ba gidigidi; emi nṣọ̀fọ kiri li gbogbo ọjọ. Nitoriti iha mi kún fun àrun ẹgbin; kò si si ibi yiyè li ara mi. Ara mi hù, o si kan bajẹ; emi ti nkerora nitori aisimi aiya mi. Oluwa, gbogbo ifẹ mi mbẹ niwaju rẹ; ikerora mi kò si pamọ́ kuro lọdọ rẹ. Aiya mi nmi-hẹlẹ, agbara mi yẹ̀ mi silẹ: bi o ṣe ti imọlẹ oju mi ni, kò si lara mi.
O. Daf 38:1-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, má fi ibinu bá mi wí! Má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà! Nítorí pé ọfà rẹ ti wọ̀ mí lára, ọwọ́ rẹ sì ti bà mí. Kò sí ibìkan tí ó gbádùn ní gbogbo ara mi nítorí ibinu rẹ; kò sì sí alaafia ninu gbogbo egungun mi, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti bò mí lórí mọ́lẹ̀; ó rìn mí mọ́lẹ̀ bí ẹrù ńlá tí ó wúwo jù fún mi. Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn, nítorí ìwà òmùgọ̀ mi, Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata, mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru. Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò, kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi. Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi; mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi. OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀, ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ. Àyà mi ń lù pì pì pì, ó rẹ̀ mí láti inú wá; ojú mi sì ti di bàìbàì.
O. Daf 38:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀. Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀. Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ; kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀; wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi. Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́ nítorí òmùgọ̀ mi. Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́. Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi, Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ; mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi. OLúWA, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ; ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ. Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀; bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.