O. Daf 37:1-22
O. Daf 37:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
MÁṢE ikanra nitori awọn oluṣe-buburu, ki iwọ ki o máṣe ilara nitori awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. Nitori ti a o ke wọn lulẹ laipẹ bi koriko, nwọn o si rọ bi eweko tutù. Gbẹkẹle Oluwa, ki o si ma ṣe rere; ma gbe ilẹ na, ki o si ma huwa otitọ. Ṣe inu-didùn si Oluwa pẹlu, on o si fi ifẹ inu rẹ̀ fun ọ. Fi ọ̀na rẹ̀ le Oluwa lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; on o si mu u ṣẹ. Yio si mu ododo rẹ jade bi imọlẹ, ati idajọ rẹ bi ọsángangan. Iwọ simi ninu Oluwa, ki o si fi sũru duro dè e; máṣe ikanra nitori ẹniti o nri rere li ọ̀na rẹ̀, nitori ọkunrin na ti o nmu èro buburu ṣẹ. Dakẹ inu-bibi, ki o si kọ̀ ikannu silẹ: máṣe ikanra, ki o má ba ṣe buburu pẹlu. Nitori ti a o ke awọn oluṣe-buburu kuro: ṣugbọn awọn ti o duro de Oluwa ni yio jogun aiye. Nitori pe nigba diẹ, awọn enia buburu kì yio si: nitotọ iwọ o fi ara balẹ wò ipò rẹ̀, kì yio si si. Ṣugbọn awọn ọlọkàn-tutù ni yio jogun aiye; nwọn o si ma ṣe inu didùn ninu ọ̀pọlọpọ alafia. Enia buburu di rikiṣi si olõtọ, o si pa ehin rẹ̀ keke si i lara. Oluwa yio rẹrin rẹ̀; nitori ti o ri pe, ọjọ rẹ̀ mbọ̀. Awọn enia buburu ti fà idà yọ, nwọn si ti fà ọrun wọn le, lati sọ talaka ati alaini kalẹ, ati lati pa iru awọn ti nrin li ọ̀na titọ. Idà wọn yio wọ̀ aiya wọn lọ, ọrun wọn yio si ṣẹ́. Ohun diẹ ti olododo ni sanju ọrọ̀ ọ̀pọ enia buburu. Nitoriti a o ṣẹ́ apa awọn enia buburu: ṣugbọn Oluwa di olododo mu. Oluwa mọ̀ ọjọ ẹni iduro-ṣinṣin: ati ilẹ-ini wọn yio wà lailai. Oju kì yio tì wọn ni igba ibi: ati li ọjọ ìyan a o tẹ́ wọn lọrun. Ṣugbọn awọn enia buburu yio ṣegbe, awọn ọta Oluwa yio dabi ẹwà oko-tutu: nwọn o run; ẹ̃fin ni nwọn o run si. Awọn enia buburu wín, nwọn kò si pada san: ṣugbọn olododo a ma ṣãnu, a si ma fi funni. Nitoriti awọn ẹni-ibukún rẹ̀ ni yio jogun aiye; awọn ẹni-egún rẹ̀ li a o ke kuro.
O. Daf 37:1-22 Yoruba Bible (YCE)
Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi; nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko; wọn óo sì rọ bí ewé. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é. Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀. Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run; ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ni yóo jogún ilẹ̀ náà. Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá; ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà: wọn óo máa gbádùn ara wọn; wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ. Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo; ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín, nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀. Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọn láti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní, láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n, ọrun wọn yóo sì dá. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo ní dára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú, ṣugbọn yóo gbé olódodo ró. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi; ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé; bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé; àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewéko wọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san; ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́. Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà, ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun.
O. Daf 37:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko, wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù. Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀. Ṣe inú dídùn sí OLúWA; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀. Fi ọ̀nà rẹ lé OLúWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é. Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan. Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLúWA, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ. Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀, má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú. Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de OLúWA àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà. Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀; nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà, wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́, wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn; ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀. Ènìyàn búburú fa idà yọ, wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn, láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀, láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin. Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ, àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́. Ohun díẹ̀ tí olódodo ní, sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú; nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n OLúWA gbé olódodo sókè. OLúWA mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé; Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi, àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé. Àwọn ọ̀tá OLúWA yóò dàbí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò. Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni; Nítorí àwọn tí OLúWA bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.