Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi; nítorí pé kíákíá ni wọn yóo gbẹ bí i koríko; wọn óo sì rọ bí ewé. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́. Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn ninu OLUWA; yóo sì fún ọ ní ohun tí ọkàn rẹ ń fẹ́. Fi ọ̀nà rẹ lé OLUWA lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé e, yóo sì ṣe ohun tí ó yẹ. Yóo mú kí ìdáláre rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀; ẹ̀tọ́ rẹ yóo sì hàn kedere bí ọ̀sán gangan. Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLUWA; fi sùúrù gbẹ́kẹ̀lé e. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí ẹni tí nǹkan ń dára fún; tabi nítorí ẹni tí ń gbèrò ibi, tí ó sì ń ṣe é. Yẹra fún ibinu; sì yàgò fún ìrúnú. Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná; ibi ni àyọrísí rẹ̀. Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run; ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA ni yóo jogún ilẹ̀ náà. Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá; ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀. Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà: wọn óo máa gbádùn ara wọn; wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ. Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo; ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín, nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀. Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọn láti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní, láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́. Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n, ọrun wọn yóo sì dá. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo ní dára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú, ṣugbọn yóo gbé olódodo ró. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi; ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé; bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó. Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé; àwọn ọ̀tá OLUWA yóo pòórá bí ẹwà ewéko wọn óo parẹ́ bí èéfín tí í parẹ́. Bí eniyan burúkú bá yá owó, kò ní san; ṣugbọn ẹni rere ní ojú àánú, ó sì lawọ́. Nítorí pé àwọn tí Ọlọrun bá bukun ni yóo jogún ilẹ̀ náà, ṣugbọn àwọn tí ó bá fi gégùn-ún yóo parun.
Kà ORIN DAFIDI 37
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 37:1-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò