O. Daf 36:5-10
O. Daf 36:5-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma. Ododo rẹ dabi awọn òke Ọlọrun; idajọ rẹ dabi ibu nla: Oluwa, iwọ pa enia ati ẹranko mọ́. Ọlọrun, iṣeun-ifẹ rẹ ti dara to! nitori na li awọn ọmọ enia yio ma gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ. Ororo ile rẹ yio tẹ wọn lọrùn gidigidi; iwọ o si mu wọn mumi ninu odò ifẹ rẹ. Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ. Mu iṣeun ifẹ rẹ pẹ si awọn ti o mọ̀ ọ; ati ododo rẹ fun awọn alaiyà diduro.
O. Daf 36:5-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run; òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Òtítọ́ rẹ dàbí òkè ńlá; ìdájọ́ rẹ sì jìn bí ibú omi. OLUWA, àtènìyàn, àtẹranko ni ò ń gbàlà. Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ níye lórí pupọ, Ọlọrun! Àwọn ọmọ eniyan a máa sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ. Wọ́n ń rí oúnjẹ jẹ ní àjẹyó ní ilé rẹ; nǹkan mímu tí ń ṣàn bí odò, ni o sì ń fún wọn mu. Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀. Túbọ̀ máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ han àwọn tí ó mọ̀ ọ́, sì máa fi òdodo rẹ han àwọn ọlọ́kàn mímọ́.
O. Daf 36:5-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ OLúWA, ó ga dé ọ̀run, òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀. Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run, àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá; ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, OLúWA. Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run! Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ. Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ. Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀. Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!