O. Daf 36

36
Ìwà ìkà
1IREKỌJA enia buburu wi ninu ọkàn mi pe; ẹ̀ru Ọlọrun kò si niwaju rẹ̀.
2Nitoriti o npọ́n ara rẹ̀ li oju ara rẹ̀, titi a o fi ri ẹ̀ṣẹ rẹ̀ lati korira;
3Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ li ẹ̀ṣẹ on ẹ̀tan: o ti fi ọgbọ́n ati iṣe rere silẹ,
4O ngbèro ìwa-ika lori ẹni rẹ̀: o gba ọ̀na ti kò dara; on kò korira ibi.
Oore Ọlọrun
5Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma.
6Ododo rẹ dabi awọn òke Ọlọrun; idajọ rẹ dabi ibu nla: Oluwa, iwọ pa enia ati ẹranko mọ́.
7Ọlọrun, iṣeun-ifẹ rẹ ti dara to! nitori na li awọn ọmọ enia yio ma gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ.
8Ororo ile rẹ yio tẹ wọn lọrùn gidigidi; iwọ o si mu wọn mumi ninu odò ifẹ rẹ.
9Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ.
10Mu iṣeun ifẹ rẹ pẹ si awọn ti o mọ̀ ọ; ati ododo rẹ fun awọn alaiyà diduro.
11Máṣe jẹ ki ẹsẹ agberaga ki o wá si mi, ki o má si jẹ ki ọwọ enia buburu ki o ṣi mi ni ipò.
12Nibẹ li awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ gbe ṣubu: a rẹ̀ wọn silẹ, nwọn kì yio si le dide.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 36: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa