O. Daf 34:4-18

O. Daf 34:4-18 Yoruba Bible (YCE)

Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù. Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀; ojú kò sì tì wọ́n. Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀, ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, a sì máa gbà wọ́n. Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í! Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀! Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní, ebi a sì máa pa wọ́n; ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWA kò ní ṣe aláìní ohun rere kankan. Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi, n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA. Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín, tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn, tí ó fẹ́ pẹ́ láyé? Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú, ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde. Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe; ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀. OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo, Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn. OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára, láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́, a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́, a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.

O. Daf 34:4-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èmi wá OLúWA, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo. Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn; ojú kò sì tì wọ́n. Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, OLúWA sì gbóhùn rẹ̀; ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. Angẹli OLúWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká ó sì gbà wọ́n. Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé OLúWA dára; ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù OLúWA, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n; ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá OLúWA kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára. Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi; èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù OLúWA. Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀; kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere? Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ. Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere; wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀. Ojú OLúWA ń bẹ lára àwọn olódodo; etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn. Ojú OLúWA korò sí àwọn tí ń ṣe búburú; láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀. Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, OLúWA a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn. OLúWA súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.