O. Daf 34:4-11
O. Daf 34:4-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi ṣe afẹri Oluwa, o si gbohùn mi; o si gbà mi kuro ninu gbogbo ìbẹru mi. Nwọn wò o, imọlẹ si mọ́ wọn: oju kò si tì wọn. Ọkunrin olupọnju yi kigbe pè, Oluwa si gbohùn rẹ̀, o si gbà a ninu gbogbo ipọnju rẹ̀: Angeli Oluwa yi awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀ ká, o si gbà wọn. Tọ́ ọ wò, ki o si ri pe, rere ni Oluwa: alabukún fun li ọkunrin na ti o gbẹkẹle e. Ẹ bẹ̀ru Oluwa, ẹnyin enia rẹ̀ mimọ́: nitoriti kò si aini fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, Awọn ọmọ kiniun a ma ṣe alaini, ebi a si ma pa wọn: ṣugbọn awọn ti nwá Oluwa, kì yio ṣe alaini ohun ti o dara. Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa.
O. Daf 34:4-11 Yoruba Bible (YCE)
Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ gbogbo ohun tí ń bà mí lẹ́rù. Wọ́n gbójú sókè sí OLUWA, wọ́n láyọ̀; ojú kò sì tì wọ́n. Olùpọ́njú ké pe OLUWA, OLUWA gbọ́ ohùn rẹ̀, ó sì gbà á ninu gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, a sì máa gbà wọ́n. Tọ́ ọ wò, kí o sì rí i pé rere ni OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá sá di í! Ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ̀yin eniyan mímọ́ rẹ̀, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀! Àwọn ọmọ kinniun a máa ṣe aláìní, ebi a sì máa pa wọ́n; ṣugbọn àwọn tí wọ́n bá ń wá OLUWA kò ní ṣe aláìní ohun rere kankan. Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi, n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA.
O. Daf 34:4-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi wá OLúWA, ó sì dá mi lóhùn; Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo. Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn; ojú kò sì tì wọ́n. Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, OLúWA sì gbóhùn rẹ̀; ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀. Angẹli OLúWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká ó sì gbà wọ́n. Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé OLúWA dára; ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù OLúWA, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́, nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n; ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá OLúWA kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára. Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi; èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù OLúWA.