O. Daf 34:17-22
O. Daf 34:17-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, OLúWA a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn. OLúWA súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là. Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n OLúWA gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀. Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́; kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn. Ibi ni ó mú ikú ìkà wá, àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi. OLúWA ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà; kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.
O. Daf 34:17-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo. Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là. Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo. O pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kò si ọkan ti o ṣẹ́ ninu wọn. Ibi ni yio pa enia buburu; ati awọn ti o korira olododo yio jẹbi. Oluwa rà ọkàn awọn iranṣẹ rẹ̀; ọkan ninu awọn ti o gbẹkẹle e kì yio jẹbi.
O. Daf 34:17-22 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́, a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́, a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là. Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀; ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn. A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn. Ibi ni yóo pa eniyan burúkú; a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi. OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada; ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi.