O. Daf 34:15-18
O. Daf 34:15-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn. Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ. Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo. Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là.
O. Daf 34:15-18 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo, Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn. OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára, láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́, a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́, a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là.
O. Daf 34:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ojú OLúWA ń bẹ lára àwọn olódodo; etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn. Ojú OLúWA korò sí àwọn tí ń ṣe búburú; láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀. Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, OLúWA a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn. OLúWA súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.