O. Daf 34:11-22
O. Daf 34:11-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wá, ẹnyin ọmọ, fi eti si mi: emi o kọ́ nyin li ẹ̀ru Oluwa. Ọkunrin wo li o nfẹ ìye, ti o si nfẹ ọjọ pipọ, ki o le ma ri rere? Pa ahọn rẹ mọ́ kuro ninu ibi, ati ète rẹ kuro li ẹ̀tan sisọ. Lọ kuro ninu ibi, ki o si ma ṣe rere; ma wá alafia, ki o si lepa rẹ̀. Oju Oluwa mbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ si ṣi si igbe wọn. Oju Oluwa kan si awọn ti nṣe buburu, lati ke iranti wọn kuro lori ilẹ. Awọn olododo nke, Oluwa si gbọ́, o si yọ wọn jade ninu iṣẹ́ wọn gbogbo. Oluwa mbẹ leti ọdọ awọn ti iṣe onirobinujẹ ọkàn; o si gbà iru awọn ti iṣe onirora ọkàn là. Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo. O pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kò si ọkan ti o ṣẹ́ ninu wọn. Ibi ni yio pa enia buburu; ati awọn ti o korira olododo yio jẹbi. Oluwa rà ọkàn awọn iranṣẹ rẹ̀; ọkan ninu awọn ti o gbẹkẹle e kì yio jẹbi.
O. Daf 34:11-22 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ tẹ́tí sí mi, n óo kọ yín ní ìbẹ̀rù OLUWA. Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín, tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn, tí ó fẹ́ pẹ́ láyé? Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú, ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde. Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe; ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀. OLUWA ń ṣọ́ àwọn olódodo, Ó sì ń dẹ etí sí igbe wọn. OLUWA fojú sí àwọn aṣebi lára, láti pa wọ́n rẹ́, kí á má sì ṣe ranti wọn mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí olódodo bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA a máa gbọ́, a sì máa gbà wọ́n kúrò ninu gbogbo ìyọnu wọn. OLUWA wà nítòsí àwọn tí ọkàn wọn bàjẹ́, a sì máa gba àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn là. Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀; ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn. A máa pa gbogbo egungun rẹ̀ mọ́; kì í jẹ́ kí ọ̀kankan fọ́ ninu wọn. Ibi ni yóo pa eniyan burúkú; a óo sì dá àwọn tí ó kórìíra olódodo lẹ́bi. OLUWA ra ẹ̀mí àwọn iranṣẹ rẹ̀ pada; ẹnikẹ́ni tí ó bá sá di í kò ní jẹ̀bi.
O. Daf 34:11-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi; èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù OLúWA. Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀; kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere? Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ. Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere; wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀. Ojú OLúWA ń bẹ lára àwọn olódodo; etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn. Ojú OLúWA korò sí àwọn tí ń ṣe búburú; láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀. Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́, OLúWA a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn. OLúWA súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là. Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀, ṣùgbọ́n OLúWA gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀. Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́; kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn. Ibi ni ó mú ikú ìkà wá, àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi. OLúWA ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà; kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.