O. Daf 33:18-22
O. Daf 33:18-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀; Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan. Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa. Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́. Ki ãnu rẹ, Oluwa, ki o wà lara wa, gẹgẹ bi awa ti nṣe ireti rẹ.
O. Daf 33:18-22 Yoruba Bible (YCE)
Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú, kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn. Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA; òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa. A láyọ̀ ninu rẹ̀, nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀. OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa bí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.
O. Daf 33:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wò ó, ojú OLúWA wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn. Ọkàn wa dúró de OLúWA; òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa. Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀, nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́. Kí àánú rẹ, OLúWA, kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.