O. Daf 33:12-22
O. Daf 33:12-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún ni fun orilẹ-ède na, Ọlọrun ẹniti Oluwa iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀. Oluwa wò lati ọrun wá, o ri gbogbo ọmọ enia. Lati ibujoko rẹ̀ o wò gbogbo araiye. O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn. Kò si ọba kan ti a ti ọwọ ọ̀pọ ogun gba silẹ: kò si alagbara kan ti a fi agbara pupọ̀ gba silẹ. Ohun asan li ẹṣin fun igbala: bẹ̃ni kì yio fi agbara nla rẹ̀ gbàni silẹ. Kiye si i, oju Oluwa mbẹ lara awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, lara awọn ti nreti ninu ãnu rẹ̀; Lati gba ọkàn wọn la lọwọ ikú, ati lati pa wọn mọ́ lãye ni igba ìyan. Ọkàn wa duro de Oluwa: on ni iranlọwọ wa ati asà wa. Nitori ti ọkàn wa yio yọ̀ niti rẹ̀, nitori ti awa ti gbẹkẹle orukọ rẹ̀ mimọ́. Ki ãnu rẹ, Oluwa, ki o wà lara wa, gẹgẹ bi awa ti nṣe ireti rẹ.
O. Daf 33:12-22 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn, àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀! OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run, ó rí gbogbo eniyan; láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí, ó wo gbogbo aráyé. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn, tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn. Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là; kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là. Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun; kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là. Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú, kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn. Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA; òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa. A láyọ̀ ninu rẹ̀, nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀. OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wa bí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.
O. Daf 33:12-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí OLúWA jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀. OLúWA wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn. Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsi ìṣe wọn. A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun; kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀. Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun; bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀. Wò ó, ojú OLúWA wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin. Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn. Ọkàn wa dúró de OLúWA; òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa. Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀, nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́. Kí àánú rẹ, OLúWA, kí ó wà lára wa, àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.