O. Daf 33:12-15
O. Daf 33:12-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún ni fun orilẹ-ède na, Ọlọrun ẹniti Oluwa iṣe; ati awọn enia na ti o ti yàn ṣe ini rẹ̀. Oluwa wò lati ọrun wá, o ri gbogbo ọmọ enia. Lati ibujoko rẹ̀ o wò gbogbo araiye. O ṣe aiya wọn bakanna; o kiyesi gbogbo iṣẹ wọn.
Pín
Kà O. Daf 33O. Daf 33:12-15 Yoruba Bible (YCE)
Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn, àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀! OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run, ó rí gbogbo eniyan; láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí, ó wo gbogbo aráyé. Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn, tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn.
Pín
Kà O. Daf 33O. Daf 33:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí OLúWA jẹ́ tirẹ̀, àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀. OLúWA wò láti ọ̀run wá; Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn. Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́ Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà, ó sì kíyèsi ìṣe wọn.
Pín
Kà O. Daf 33