O. Daf 30:1-3
O. Daf 30:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o kokiki rẹ, Oluwa; nitori iwọ li o gbé mi leke, ti iwọ kò si jẹ ki awọn ọta mi ki ó yọ̀ mi. Oluwa Ọlọrun mi, emi kigbe pè ọ, iwọ si ti mu mi lara da. Oluwa, iwọ ti yọ ọkàn mi jade kuro ninu isa-okú: iwọ o si pa mi mọ́ lãye, ki emi ki o má ba lọ sinu iho.
O. Daf 30:1-3 Yoruba Bible (YCE)
N óo yìn ọ́, OLUWA, nítorí pé o ti yọ mí jáde; o kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. OLUWA, Ọlọrun mi, mo ké pè ọ́, o sì wò mí sàn. OLUWA, o ti yọ mí kúrò ninu isà òkú o sọ mí di ààyè láàrin àwọn tí wọ́n ti wọ inú kòtò.
O. Daf 30:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò kókìkí i rẹ, OLúWA, nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí. OLúWA Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́ ìwọ sì ti wò mí sàn. OLúWA, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú, mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.