O. Daf 3:2-5
O. Daf 3:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀pọlọpọ li awọn ti o nwi niti ọkàn mi pe, Iranlọwọ kò si fun u nipa ti Ọlọrun. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke. Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá. Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin
O. Daf 3:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé, Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀! Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi, ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí, nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.
O. Daf 3:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela. Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, OLúWA; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè. OLúWA ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela. Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí OLúWA ni ó ń gbé mi ró.