O. Daf 3:1-6
O. Daf 3:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, awọn ti nyọ mi li ẹnu ti npọ̀ to yi! ọ̀pọlọpọ li awọn ti o dide si mi. Ọ̀pọlọpọ li awọn ti o nwi niti ọkàn mi pe, Iranlọwọ kò si fun u nipa ti Ọlọrun. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke. Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá. Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin, Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka.
O. Daf 3:1-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ! Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi! Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé, Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀! Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi, ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí, nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká kò le bà mí lẹ́rù.
O. Daf 3:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, báwo ni àwọn ọ̀tá mi ṣe pọ̀ tó báyìí! Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé “Ọlọ́run kò nígbà á là.” Sela. Ṣùgbọ́n ìwọ ni asà yí mi ká, OLúWA; ìwọ fi ògo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè. OLúWA ni mo kígbe sókè sí, ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela. Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn; mo sì tún padà jí, nítorí OLúWA ni ó ń gbé mi ró. Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.