OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ! Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi! Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé, Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀! Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi, ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà. Mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí, nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká kò le bà mí lẹ́rù.
Kà ORIN DAFIDI 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 3:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò