O. Daf 29:1-4
O. Daf 29:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ FI fun Oluwa, ẹnyin ọmọ awọn alagbara, ẹ fi ogo ati agbara fun Oluwa. Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́. Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀. Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla.

O. Daf 29:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA, ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ. Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀, ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀. À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun, Ọlọrun ológo ń sán ààrá, Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi. Ohùn OLUWA lágbára, ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá.
O. Daf 29:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ fi fún OLúWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, Ẹ fi fún OLúWA, ògo àti alágbára. Fi fún OLúWA, àní ògo orúkọ rẹ̀; sin OLúWA nínú ẹwà ìwà mímọ́. Ohùn OLúWA n ré àwọn omi kọjá; Ọlọ́run ògo sán àrá, OLúWA san ara. Ohùn OLúWA ní agbára; ohùn OLúWA kún fún ọláńlá.