ORIN DAFIDI 29:1-4

ORIN DAFIDI 29:1-4 YCE

Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA, ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ. Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀, ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀. À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun, Ọlọrun ológo ń sán ààrá, Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi. Ohùn OLUWA lágbára, ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá.