O. Daf 27:11-14
O. Daf 27:11-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Kọ́ mi li ọ̀na rẹ, Oluwa, ki o si tọ́ mi li ọ̀na titọ, nitori awọn ọta mi. Máṣe fi mi le ifẹ awọn ọta mi lọwọ; nitori awọn ẹlẹri eke dide si mi, ati iru awọn ti nmí imí-ìkà. Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alãye. Duro de Oluwa; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni, duro de Oluwa.
O. Daf 27:11-14 Yoruba Bible (YCE)
Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi. Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́; nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi, ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà. Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbà ní ilẹ̀ alààyè. Dúró de OLUWA, ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí, àní, dúró de OLUWA.
O. Daf 27:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLúWA, kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú nítorí àwọn ọ̀tá mi. Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́, nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi, wọ́n sì mí ìmí ìkà. Èmi ní ìgbàgbọ́ pé, èmi yóò rí ìre OLúWA ní ilẹ̀ alààyè. Dúró de OLúWA; kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le àní dúró de OLúWA.