O. Daf 25:16-22
O. Daf 25:16-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju. Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi. Wò ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ mi jì mi. Wò awọn ọta mi, nwọn sá pọ̀; nwọn si korira mi ni irira ìka. Pa ọkàn mi mọ́, ki o si gbà mi: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi; nitori mo gbẹkẹ̀ mi le ọ. Jẹ ki ìwa-titọ ati iduro-ṣinṣin ki o pa mi mọ́: nitoriti mo duro tì ọ. Rà Israeli pada, Ọlọrun, kuro ninu ìṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.
O. Daf 25:16-22 Yoruba Bible (YCE)
Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi; nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò; kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi. Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní, ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi. Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí; má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí, nítorí ìwọ ni mo sá di. Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́, nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Ọlọrun, ra Israẹli pada, kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.
O. Daf 25:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú. Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi. Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì. Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn. Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi. Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́. Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!