ORIN DAFIDI 25:16-22

ORIN DAFIDI 25:16-22 YCE

Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi; nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò; kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi. Wo ìpọ́njú ati ìdààmú mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí. Wo iye ọ̀tá tí èmi nìkan ní, ati irú ìkórìíra ìkà tí wọ́n kórìíra mi. Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí; má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí, nítorí ìwọ ni mo sá di. Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́, nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé. Ọlọrun, ra Israẹli pada, kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.