O. Daf 25:1-5
O. Daf 25:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, iwọ ni mo gbé ọkàn mi soke si. Ọlọrun mi, emi gbẹkẹle ọ: máṣe jẹ ki oju ki o ti mi, máṣe jẹ ki awọn ọta mi ki o yọ̀ mi. Lõtọ, maṣe jẹ ki oju ki o tì ẹnikẹni ti o duro tì ọ: awọn ti nṣẹ̀ li ainidi ni oju yio tì. Fi ọ̀na rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tirẹ. Sin mi li ọ̀na otitọ rẹ, ki o si kọ́ mi: nitori iwọ li Ọlọrun igbala mi; iwọ ni mo duro tì li ọjọ gbogbo.
O. Daf 25:1-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìwọ ni mo gbé ojú ẹ̀bẹ̀ sókè sí. Ọlọrun mi, ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé, má jẹ́ kí ojú ó tì mí; má jẹ́ kí ọ̀tá ó yọ̀ mí. OLUWA, má jẹ́ kí ojú ó ti ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọ; àwọn ọ̀dàlẹ̀ eniyan ni kí ojú ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLUWA, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ. Tọ́ mi sí ọ̀nà òtítọ́ rẹ, sì máa kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọrun olùgbàlà mi; ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé ní ọjọ́ gbogbo.
O. Daf 25:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí. Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ; Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí. Ẹni tí ó dúró tì ọ́ ojú kì yóò tì í, àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí ni kí ojú kí ó tì. Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, OLúWA, kọ mi ní ipa tìrẹ; ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi, Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.