O. Daf 24:1-10
O. Daf 24:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
TI Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀; aiye, ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ̀. Nitoriti o fi idi rẹ̀ sọlẹ lori okun, o si gbé e kalẹ lori awọn iṣan-omi. Tani yio gùn ori oke Oluwa lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ́ rẹ̀? Ẹniti o li ọwọ mimọ́, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti kò si bura ẹ̀tan. On ni yio ri ibukún gbà lọwọ Oluwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun igbala rẹ̀. Eyi ni iran awọn ti nṣe afẹri rẹ̀, ti nṣe afẹri rẹ, Ọlọrun Jakobu. Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ki a si gbé nyin soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa. Tali Ọba ogo yi? Oluwa ti o le, ti o si lagbara, Oluwa ti o lagbara li ogun. Ẹ gbé ori nyin soke, ẹnyin ẹnu-ọ̀na; ani ki ẹ gbé wọn soke, ẹnyin ilẹkun aiyeraiye: ki Ọba ogo ki o wọ̀ inu ile wa. Tali Ọba ogo yi? Oluwa awọn ọmọ-ogun; on na li Ọba ogo.
O. Daf 24:1-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀; nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi. Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ? Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun, tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn, tí kò sì búra èké. Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA, tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀. Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA, àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA tí ó ní ipá tí ó sì lágbára, OLUWA tí ó lágbára lógun. Ẹ ṣí sílẹ̀ gbayau, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn, ẹ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo lè wọlé. Ta ni Ọba ògo yìí? OLUWA àwọn ọmọ ogun, òun ni Ọba ògo náà.
O. Daf 24:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ti OLúWA ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀; Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi. Ta ni yóò gun orí òkè OLúWA lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké. Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ OLúWA, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀. Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela. Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà; Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé! Kí ọba ògo le è wọlé. Ta ni ọba ògo náà? OLúWA tí ó lágbára tí ó sì le, OLúWA gan an, tí ó lágbára ní ogun. Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà; kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé, kí Ọba ògo le è wọlé wá. Ta ni Ọba ògo náà? OLúWA àwọn ọmọ-ogun Òun ni Ọba ògo náà. Sela.