O. Daf 21:5-7
O. Daf 21:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ogo rẹ̀ pọ̀ ni igbala rẹ: iyìn ati ọlánla ni iwọ fi si i lara. Nitori iwọ ti ṣe e li ẹni-ibukún fun jùlọ titi aiye: iwọ si fi oju rẹ mu u yọ̀ gidigidi. Nitori ti ọba gbẹkẹle Oluwa, ati nipa ãnu Ọga-ogo kì yio ṣipò pada.
Pín
Kà O. Daf 21O. Daf 21:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́; o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀. Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae; o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀. Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; a kò ní ṣí i ní ipò pada, nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀.
Pín
Kà O. Daf 21O. Daf 21:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un; ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ. Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un: ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀. Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú OLúWA; nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà kì yóò sípò padà.
Pín
Kà O. Daf 21