O. Daf 19:12-14
O. Daf 19:12-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tali o le mọ̀ iṣina rẹ̀? wẹ̀ mi mọ́ kuro ninu iṣiṣe ìkọkọ mi. Fà iranṣẹ rẹ sẹhin pẹlu kuro ninu ẹ̀ṣẹ ikugbu: máṣe jẹ ki nwọn ki o jọba lori mi: nigbana li emi o duro ṣinṣin, emi o si ṣe alaijẹbi kuro ninu ẹ̀ṣẹ nla nì. Jẹ ki ọ̀rọ ẹnu mi, ati iṣaro ọkàn mi, ki o ṣe itẹwọgba li oju rẹ, Oluwa, agbara mi, ati oludande mi.
O. Daf 19:12-14 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ta ni lè mọ àṣìṣe ara rẹ̀? Wẹ̀ mí mọ́ ninu àṣìṣe àìmọ̀ mi. Pa èmi iranṣẹ rẹ mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀-ọ́n-mọ̀-dá; má jẹ́ kí wọ́n jọba lórí mi. Nígbà náà ni ara mi yóo mọ́, n kò sì ní jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, ati àṣàrò ọkàn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, OLUWA ibi ààbò mi ati olùràpadà mi.
O. Daf 19:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀? Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́. Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá; má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi. Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin, èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Ìwọ OLúWA àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.