O. Daf 19:1-4
O. Daf 19:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han. Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn. Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn. Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun.
O. Daf 19:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun, òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbà òru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn. Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn; sibẹ ìró wọn la gbogbo ayé já, ọ̀rọ̀ wọn sì dé òpin ayé. Ó pàgọ́ fún oòrùn lójú ọ̀run
O. Daf 19:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run; Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́; wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́. Kò sí ohùn tàbí èdè níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé, ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé. Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.