O. Daf 18:25-50
O. Daf 18:25-50 Bibeli Mimọ (YBCV)
Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu; fun ẹniti o duro-ṣinṣin ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni diduro-ṣinṣin. Fun ọlọkàn-mimọ́ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni ọlọkàn-mimọ́; ati fun ọlọkàn-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn li onroro. Nitori iwọ o gbà awọn olupọnju; ṣugbọn iwọ o sọ oju igberaga kalẹ. Nitori iwọ ni yio tàn fitila mi: Oluwa Ọlọrun mi yio tàn imọlẹ si òkunkun mi. Nitori pe pẹlu rẹ emi sure là inu ogun lọ: ati pẹlu Ọlọrun mi emi fò odi kan. Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọ̀na rẹ̀ pé: a ti ridi ọ̀rọ Oluwa: on li apata fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi. O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. Emi ti le awọn ọta mi, emi si bá wọn: bẹ̃li emi kò pada sẹhin titi a fi run wọn. Emi ṣá wọn li ọgbẹ ti nwọn kò fi le dide, nwọn ṣubu li abẹ ẹsẹ mi. Nitoriti iwọ fi agbara di mi li àmure si ogun na: iwọ ti mu awọn ti o dide si mi tẹriba li abẹ ẹsẹ mi. Iwọ si yi ẹhin awọn ọta mi pada fun mi pẹlu; emi si pa awọn ti o korira mi run. Nwọn kigbe, ṣugbọn kò si ẹniti o gbà wọn; ani si Oluwa, ṣugbọn kò dá wọn li ohùn. Nigbana ni mo gún wọn kunna bi ekuru niwaju afẹfẹ: mo kó wọn jade bi ohun ẹ̀gbin ni ita. Iwọ ti yọ mi kuro ninu ìja awọn enia; iwọ fi mi jẹ olori awọn orilẹ-ède: enia ti emi kò ti mọ̀, yio si ma sìn mi. Bi nwọn ti gburo mi, nwọn o gbà mi gbọ́: awọn ọmọ àjeji yio fi ẹ̀tan tẹ̀ ori wọn ba fun mi. Aiya yio pá awọn alejo, nwọn o si fi ibẹ̀ru jade ni ibi kọlọfin wọn. Oluwa mbẹ; olubukún si li apáta mi; ki a si gbé Ọlọrun igbala mi leke. Ọlọrun li o ngbẹsan mi, ti o si nṣẹ́ awọn enia fun mi. O gbà mi lọwọ awọn ọta mi: pẹlupẹlu iwọ gbé mi leke jù awọn ti o dide si mi lọ; iwọ ti gbà mi lọwọ ọkunrin alagbara nì. Nitorina li emi ṣe fi iyìn fun ọ, Oluwa, li awujọ awọn orilẹ-ède, emi o si ma kọrin iyìn si orukọ rẹ. Ẹniti o fi igbala nla fun Ọba rẹ̀; o si fi ãnu hàn fun Ẹni-ororo rẹ̀, fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ lailai.
O. Daf 18:25-50 Yoruba Bible (YCE)
Ò máa dúró ti àwọn tí ó dúró tì ọ́, ò sì máa ṣe àṣepé fún àwọn tí ó pé; mímọ́ ni ọ́ sí àwọn tí ọkàn wọn mọ́, ṣugbọn àwọn alárèékérekè ni o fi ọgbọ́n tayọ. Nítorí tí o máa ń gba àwọn onírẹ̀lẹ̀ là, ṣugbọn o máa ń rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀. Nítorí ìwọ ni o mú kí àtùpà mi máa tàn, OLUWA, Ọlọrun mi ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, mo lè run ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun, àní, pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọrun mi, mo lè fo odi ìlú. Ní ti Ọlọrun, ọ̀nà rẹ̀ pé, pípé ni ọ̀rọ̀ OLUWA; òun sì ni ààbò fún gbogbo àwọn tí ó sá di í. Ta tún ni Ọlọrun, bíkòṣe OLUWA? Àbí, ta ni àpáta, àfi Ọlọrun wa? Ọlọrun tí ó gbé agbára wọ̀ mí, tí ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó fi eré sí mi lẹ́sẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín, ó sì fún mi ní ààbò ní ibi ìsásí. Ó kọ́ mi ní ogun jíjà tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi lè fa ọrun idẹ. O ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ó gbé mi ró, ìrànlọ́wọ́ rẹ sì ni ó sọ mí di ẹni ńlá. O la ọ̀nà tí ó gbòòrò fún mi, n kò sì fi ẹsẹ̀ rọ́. Mo lé àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ mi sì tẹ̀ wọ́n, n kò bojú wẹ̀yìn títí a fi pa wọ́n run. Mo ṣá wọn lọ́gbẹ́, wọn kò lè dìde, wọ́n ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ mi. O gbé agbára ogun wọ̀ mí; o sì mú àwọn tí ó dìde sí mi wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ mi. O mú kí àwọn ọ̀tá mi máa sá níwájú mi, mo sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. Wọ́n kígbe pé, “Ẹ gbà wá o!” Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó gbà wọ́n, wọ́n ké pe OLUWA, ṣugbọn kò dá wọn lóhùn. Mo lọ̀ wọ́n lúbúlúbú bí eruku tí afẹ́fẹ́ ń gbá lọ, mo dà wọ́n nù bí ẹni da omi ẹrẹ̀ nù. O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan, o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí. Bí wọ́n bá ti gbúròó mi ni wọ́n ń gbọ́ràn sí mi lẹ́nu; àwọn àjèjì ń fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba, wọ́n ń wá ojurere mi. Àyà pá àwọn àlejò, wọ́n sì fi ìbẹ̀rùbojo sá jáde kúrò ní ibi tí wọ́n sápamọ́ sí. OLUWA wà láàyè! Ẹni ìyìn ni àpáta mi! Ẹni àgbéga ni Ọlọrun ìgbàlà mi! Ọlọrun tí ó ń gbẹ̀san fún mi, tí ó sì ń tẹ orí àwọn eniyan ba fún mi; Ọlọrun tí ó gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi; tí ó sì gbé mi ga ju àwọn abínú-ẹni lọ; ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ àwọn ẹni ipá tí ó dìde sí mi. Nítorí náà ni èmi ó ṣe máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, OLUWA, èmi ó sì máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ. Ó fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ han ẹni àmì òróró rẹ̀, àní Dafidi ati ìrandíran rẹ̀ títí lae.
O. Daf 18:25-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́, sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi, Sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́, ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò. O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀. Ìwọ, OLúWA, jẹ́ kí fìtílà mi kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ; pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan. Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ OLúWA òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò. Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe OLúWA? Ta ní àpáta bí kò ṣe OLúWA wa? Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè ó sì mú ọ̀nà mi pé. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga. Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà; apá mi lè tẹ ọrùn idẹ Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró; àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá. Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi, kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀. Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n. Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde; Wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi. Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n, àní sí OLúWA, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn. Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́; mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀. Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí, ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́; àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi. Àyà yóò pá àlejò; wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn. OLúWA wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi! Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi. Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi, tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi, tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí. Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ; lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí. Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ OLúWA; Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ. Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá; ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀, fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.